Revelation 14:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo tún rí angẹli mìíràn tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run. Ó mú ìyìn rere ayérayé lọ́wọ́ láti kéde rẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ninu ayé, ninu gbogbo ẹ̀yà ati gbogbo orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ri angẹli miran nfò li agbedemeji ọrun, ti on ti ihinrere ainipẹkun lati wãsu fun awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, ati fun gbogbo orilẹ, ati ẹya, ati ède, ati enia,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn ń fò ní àárin méjì ọ̀run, pẹ̀lú Ìyìn rere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.