Revelation 14:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Angẹli mìíràn tẹ̀lé ti àkọ́kọ́, ó ní, “Ó ti tú! Babiloni ìlú ńlá nnì ti tú! Ìlú tí ó fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní ọtí àgbèrè rẹ̀ mu, tí ó mú ibinu Ọlọrun wá, ó ti tú!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Angẹli miran si tẹ̀le e, o nwipe, Babiloni wó, Babiloni ti o tobi nì wó, eyiti o ti nmú gbogbo orilẹ-ède mu ninu ọti-waini ibinu àgbere rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ańgẹ́lì mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “Ó ṣubú, Bábílónì ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!”