Revelation 15:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo tún rí ohun tí ó dàbí òkun dígí tí iná wà ninu rẹ̀. Àwọn kan dúró lẹ́bàá òkun dígí náà, àwọn tí wọ́n ti ṣẹgun ẹranko náà ati ère rẹ̀, ati iye orúkọ rẹ̀. Wọ́n mú hapu Ọlọrun lọ́wọ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ri bi ẹnipe òkun digí ti o dàpọ pẹlu iná: awọn ti o si duro lori okun digi yi jẹ awọn ti nwọn ti ṣẹgun ẹranko na, ati aworan rẹ̀, ati ami rẹ̀ ati iye orukọ rẹ̀, nwọn ni dùru Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì rí bí ẹni pé, òkun dígí tí o dàpọ̀ pẹ̀lú iná: àwọn tí ó sì dúró lórí òkun dígí yìí jẹ́ àwọn ti wọ́n sẹ́gun ẹranko náà, àti àwòrán rẹ̀, àti àmì rẹ̀ àti nọ́ḿba orúkọ rẹ̀, wọn ní Haàpù Ọlọ́run.