Revelation 15:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, Oluwa? Ta ni kò ní fi ògo fún orúkọ rẹ? Nítorí ìwọ nìkan ni ó pé, nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá, wọn yóo júbà níwájú rẹ, nítorí òdodo rẹ farahàn gbangba.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tani kì yio bẹ̀ru, Oluwa, ti kì yio si fi ogo fun orukọ rẹ? nitori iwọ nikanṣoṣo ni mimọ́: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio si wá, ti yio si foribalẹ niwaju rẹ; nitori a ti fi idajọ rẹ hàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni kì yóò bẹ̀rù, Olúwa, tí kì yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ̀? Nítorí ìwọ níkanṣoṣo ni mímọ́. Gbogbo àwọn orílẹ èdè mi yóò sì wá, ti yóò sì foribalẹ̀ níwájú rẹ, nítorí a ti fi ìdájọ́ rẹ hàn.”