Revelation 15:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Inú Tẹmpili wá kún fún èéfín ògo Ọlọrun ati ti agbára rẹ̀. Kò sí ẹni tí ó lè wọ inú Tẹmpili títí tí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn meje ti àwọn angẹli meje náà fi parí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tẹmpili na si kún fun ẹ̃fin lati inu ogo Ọlọrun ati agbara rẹ̀ wá; ẹnikẹni kò si le wọ̀ inu tẹmpili na lọ titi a fi mu iyọnu mejeje awọn angẹli meje na ṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tẹ́ḿpìlì náà sì kún fún èéfín láti inú ògo Ọlọ́run àti agbára rẹ̀ wá; ẹnikẹ́ni kò sì lè wọ inú tẹ́ḿpìlì náà lọ títí a fi mú ìyọnu méjèèje àwọn ańgẹ́lì méje náà ṣẹ.