Revelation 16:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀mí Èṣù ni àwọn ẹ̀mí náà, wọ́n sì lè ṣe ohun abàmì. Wọ́n jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba ní gbogbo ayé, láti kó wọn jọ fún ogun ní ọjọ́ ńlá ti Ọlọrun alágbára jùlọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ẹmi èṣu ni wọn, ti nṣe iṣẹ-iyanu, awọn ti njade lọ sọdọ awọn ọba gbogbo ilẹ aiye, lati gbá wọn jọ si ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ẹ̀mí èṣù ni wọ́n, tí ń ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tí ń jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé, láti gbá wọn jọ sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olúdàmarè.