Revelation 16:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yìnyín ńláńlá tí ó tóbi tó ọlọ ata wá bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ lu eniyan láti ojú ọ̀run. Àwọn eniyan wá ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun nítorí ìparun tí yìnyín yìí ń fà, nítorí ó ń ṣe ọpọlọpọ ijamba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yinyín nla, ti ọkọ̃kan rẹ̀ to talenti ni ìwọ̀n, si bọ́ lù awọn enia lati ọrun wà: awọn enia si sọ̀rọ-òdi si Ọlọrun nitori iyọnu yinyín na; nitoriti iyọnu rẹ̀ na pọ̀ gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yìnyín ńlá, tí ọkọkan rẹ̀ tó talẹ́ntì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà: Àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà; nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi.