Revelation 16:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oòrùn bẹ̀rẹ̀ sí jó àwọn eniyan bí iná ńlá, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun tí ó ní àṣẹ lórí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn wọnyi, dípò kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n fi ògo fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si fi õru nla jo awọn enia lara, nwọn si sọ̀rọ-òdi si orukọ Ọlọrun, ẹniti o li agbara lori iyọnu wọnyi: nwọn kò si ronupiwada lati fi ogo fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A sì fi oru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.