Revelation 17:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àwo meje náà tọ̀ mí wá, ó ní, “Wá kí n fi ìdájọ́ tí ń bọ̀ sórí gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà hàn ọ́, ìlú tí a kọ́ sójú ọpọlọpọ omi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ỌKAN ninu awọn angẹli meje na ti o ni ìgo meje wọnni si wá, o si ba mi sọrọ wipe, Wá nihin; emi o si fi idajọ àgbere nla nì ti o joko lori omi pupọ̀ han ọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje náà tí ó ní ìgò méje wọ̀n-ọn-nì sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín; èmi ó sì fi ìdájọ́ àgbèrè ńlá ní tí ó jókòó lórí omi púpọ̀ han ọ: