Revelation 17:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí jẹ́ ọba mẹ́wàá. Ṣugbọn wọn kò ì tíì joyè. Wọn óo gba àṣẹ fún wakati kan, àwọn ati ẹranko náà ni yóo jọ lo àṣẹ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwo mẹwa ti iwọ si ri nì ọba mẹwa ni nwọn, ti nwọn kò iti gba ijọba; ṣugbọn nwọn gba ọla bi ọba pẹlu ẹranko na fun wakati kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwo mẹ́wáà tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba ọlá bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan.