Revelation 17:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn yóo bá Ọ̀dọ́ Aguntan náà jagun, ṣugbọn Ọ̀dọ́ Aguntan náà yóo ṣẹgun wọn nítorí pé òun ni Oluwa àwọn oluwa ati Ọba àwọn ọba. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu Ọ̀dọ́ Aguntan náà ninu ìjà ati ìṣẹ́gun náà ni àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí a pè, tí a sì yàn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn wọnyi ni yio si mã ba Ọdọ-Agutan jagun, Ọdọ-Agutan na yio si ṣẹgun wọn: nitori on ni Oluwa awọn oluwa, ati Ọba awọn ọba: awọn ti o si wà pẹlu rẹ̀, ti a pè, ti a yàn, ti nwọn si jẹ olõtọ yio si ṣẹgun pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti Ọba àwọn ọba: Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtọ́ yóò sì sẹ́gun pẹ̀lú.”