Revelation 17:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo wá rí obinrin náà tí ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun ní àmuyó, pẹlu ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu. Ìyanu ńlá ni ó jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí obinrin náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ri obinrin na mu ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́, ati ẹ̀jẹ awọn ajẹrikú Jesu li amuyo: nigbati mo si ri i, ẹnu yà mi gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jésù ní àmuyó. Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi.