Revelation 18:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo dúró ní òkèèrè nítorí ẹ̀rù tí yóo máa bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀. Wọn óo sọ pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ọ! Ìlú ńlá, Babiloni ìlú alágbára! Nítorí ní wakati kan ni ìparun dé bá ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o duro li okere rére nitori ibẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, Babiloni, ilu alagbara ni! nitori ni wakati kan ni idajọ rẹ de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, Bábílónì ìlú alágbára nì! Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’