Revelation 18:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ní, “Èso tí o fẹ́ràn kò sí mọ́, gbogbo ìgbé-ayé fàájì ati ti ìdẹ̀ra ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ, o kò tún ní rí irú rẹ̀ mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn eso ti ọkàn rẹ nṣe ifẹkufẹ si, sì lọ kuro lọdọ rẹ, ati ohun gbogbo ti o dùn ti o si dara ṣegbe mọ ọ loju, a kì yio si tún ri wọn mọ́ lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kufẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé.