Revelation 18:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn oníṣòwò wọnyi, tí wọ́n ti di olówó ninu rẹ̀ yóo dúró ní òkèèrè nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀, wọn óo máa sunkún, wọn óo máa ṣọ̀fọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn oniṣowo nkan wọnyi, ti a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọrọ̀, yio duro li òkere rére nitori ìbẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã sọkun, nwọn o si mã ṣọ̀fọ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè rére nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ oró rẹ̀, wọn o máa sọ́kún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀,