Revelation 18:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn óo máa wí pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà! Ìlú tí ó wọ aṣọ funfun, ati aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa. Ìlú tí wúrà pọ̀ níbẹ̀ ati òkúta iyebíye ati ìlẹ̀kẹ̀!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wipe, Ègbé, egbé ni fun ilu nla nì, ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, ati ti elese aluko, ati ti ododó, ati ti a si fi wura ṣe lọṣọ́, pẹlu okuta iyebiye ati perli!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wí pé: “ ‘Ẹ̀gbẹ́! Ẹ̀gbé, ni fún ìlú ńlá nì, tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe lọ́sọ̀ọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti pẹrílì!