Revelation 18:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní wakati kan péré ni gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ run!” Nígbà náà ni gbogbo ọ̀gá àwọn awakọ̀ ojú omi, ati gbogbo àwọn tí ó ń wọ ọkọ̀ ati àwọn atukọ̀ ati àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ ojú omi òkun lọ dúró ní òkèèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe ni wakati kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tobẹ̃ di asan. Ati olukuluku olori ọkọ̀, ati olukuluku ẹniti nrin oju omi lọ si ibikibi, ati awọn ti nṣiṣẹ, ninu ọkọ̀, ati awọn ti nṣowo oju okun duro li òkere rére,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’ “Àti olúkulùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ìbikíbí, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú òkun dúró ní òkèrè réré,