Revelation 18:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bu yẹ̀ẹ̀pẹ̀ sórí ara wọn, wọ́n ń sunkún, wọ́n ń ṣọ̀fọ̀. Wọ́n ní, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ìlú ńlá náà, níbi tí gbogbo àwọn tí wọn ní ọkọ̀ lójú òkun ti di ọlọ́rọ̀ nípa ọrọ̀ rẹ̀, nítorí ní wakati kan ó ti di ahoro!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kù ekuru si ori wọn, nwọn kigbe, nwọn sọkun, nwọn si nṣọfọ, wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, ninu eyi ti a sọ gbogbo awọn ti o ni ọkọ̀ li okun di ọlọrọ̀ nipa ohun iyebiye rẹ̀! nitoripe ni wakati kan a sọ ọ di ahoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé: “ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà, nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ ní òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀! Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.