Revelation 18:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Iná àtùpà kan kò ní tàn ninu rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́. Nígbà kan rí àwọn oníṣòwò rẹ ni àwọn gbajúmọ̀ ninu ayé. O fi ìwà àjẹ́ tan gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati imọlẹ fitila ni kì yio si tàn ninu rẹ mọ́ lai; a ki yio si gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́ lai: nitoripe awọn oniṣowo rẹ li awọn ẹni nla aiye; nitoripe nipa oṣó rẹ li a fi tàn orilẹ-ède gbogbo jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé; a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé: nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé; nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀ èdè gbogbo jẹ.