Revelation 18:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ti mu àmuyó ninu ọtí àgbèrè rẹ̀, ọtí tí ó fa ibinu Ọlọrun. Àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn oníṣòwò ilẹ̀ ayé ti di olówó nípa ìwà jayéjayé rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori nipa ọti-waini irunu àgbere rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ede ṣubu, awọn ọba aiye si ti ba a ṣe àgbere, ati awọn oniṣowo aiye si di ọlọrọ̀ nipa ọ̀pọlọpọ wọbia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú. Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè, àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”