Revelation 19:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Idà mímú yọ jáde ní ẹnu rẹ̀, tí yóo fi ṣẹgun àwọn orílẹ̀-èdè, nítorí òun ni yóo jọba lórí wọn pẹlu ọ̀pá irin. Òun ni yóo pọn ọtí ibinu ati ti ẹ̀san Ọlọrun Olodumare.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lati ẹnu rẹ̀ ni idà mimu ti njade lọ, ki o le mã fi iṣá awọn orilẹ-ède: on o si mã fi ọpá irin ṣe akoso wọn: o si ntẹ ifúnti irunu ati ibinu Ọlọrun Olodumare.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi ṣá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn:” ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè.