Revelation 19:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo tún rí angẹli kan tí ó dúró ninu oòrùn, ó kígbe sí àwọn ẹyẹ tí ń fò lágbedeméjì ọ̀run pé, “Ẹ wá péjọ sí ibi àsè ńlá Ọlọrun,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ri angẹli kan duro ninu õrùn; o si fi ohùn rara kigbe, o nwi fun gbogbo awọn ẹiyẹ ti nfò li agbedemeji ọrun pe, Ẹ wá, ẹ si kó ara nyin jọ pọ̀ si àse-alẹ nla Ọlọrun;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì rí ańgẹ́lì kan dúró nínú òòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè-ńlá Ọlọ́run;