Revelation 19:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òtítọ́ ati òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí ó ti dájọ́ fún gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà, tí ó fi àgbèrè rẹ̀ ba ayé jẹ́. Ó ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀ lára rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori otitọ ati ododo ni idajọ rẹ̀: nitori o ti ṣe idajọ àgbere nla nì, ti o fi àgbere rẹ̀ ba ilẹ aiye jẹ, o si ti gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀ lọwọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀. Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì, tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ́ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”