Revelation 19:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo tún gbọ́ ohùn kan bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan, ati bí ìró ọpọlọpọ omi, ati bí sísán ààrá líle, ohùn náà sọ pé, “Haleluya! Nítorí Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare jọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn ọ̀pọlọpọ enia, ati bi iró omi pupọ̀, ati bi iró ãrá nlanla, nwipe Halleluiah: nitori Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare, njọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé: “Halelúyà! Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jọba.