Revelation 2:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Má bẹ̀rù ohunkohun tí ò ń bọ̀ wá jìyà. Èṣù yóo gbé ẹlòmíràn ninu yín jù sinu ẹ̀wọ̀n láti fi dán yín wò. Fún ọjọ́ mẹ́wàá ẹ óo ní ìṣòro pupọ. Ṣugbọn jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú, Èmi yóo sì fún ọ ní adé ìyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Máṣe bẹ̀ru ohunkohun tì iwọ mbọ̀ wá jiya rẹ̀: kiyesi i, Èṣu yio gbé ninu nyin jù sinu tubu, ki a le dán nyin wò; ẹnyin o si ni ipọnju ni ijọ mẹwa: iwọ sa ṣe olõtọ de oju ikú, emi ó si fi ade ìye fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Máṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsí i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túúbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá: ìwọ sa se olóòtọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ