Revelation 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn mo ní àwọn nǹkan díẹ̀ wí sí ọ. O ní àwọn kan láàrin ìjọ tí wọ́n gba ẹ̀kọ́ Balaamu, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti fi ohun ìkọsẹ̀ siwaju àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n fi ń jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà, tí wọ́n tún ń ṣe àgbèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn mo ni nkan diẹ iwi si ọ, nitoriti iwọ ni awọn ti o dì ẹkọ́ ti Balaamu mu nibẹ̀, ẹniti o kọ́ Balaku lati mu ohun ikọsẹ̀ wá siwaju awọn ọmọ Israeli, lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa, ati lati mã ṣe àgbere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí o di ẹ̀kọ́ Báláámù mú nibẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Bálákì láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá ṣíwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè.