Revelation 2:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn mo ní nǹkan wí sí ọ. O gba obinrin tí wọn ń pè ní Jesebẹli láàyè. Ó ń pe ara rẹ̀ ní aríran, ó ń tan àwọn iranṣẹ mi jẹ, ó ń kọ́ wọn láti ṣe àgbèrè ati láti jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn eyi ni mo ri wi si ọ, nitoriti iwọ fi aye silẹ fun obinrin nì Jesebeli ti o pè ara rẹ̀ ni woli, o si nkọ awọn iranṣẹ mi o si ntan wọn lati mã ṣe àgbere, ati lati mã jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sì ọ: Nítorí tí ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún obìnrin Jésébẹ́lì tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípaṣ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sì òrìṣà.