Revelation 2:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo dá a dùbúlẹ̀ àìsàn. Ìṣòro pupọ ni yóo bá àwọn tí wọ́n bá bá a ṣe àgbèrè, àfi bí wọ́n bá rí i pé iṣẹ́ burúkú ni ó ń ṣe, tí wọn kò sì bá a lọ́wọ́ ninu rẹ̀ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, emi ó gbe e sọ si ori akete, ati awọn ti mba a ṣe panṣaga li emi o fi sinu ipọnju nla, bikoṣe bi nwọn ba ronupiwada iṣẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.