Revelation 2:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo mọ̀ pé o ní ìṣòro; ati pé o ṣe aláìní, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́rọ̀ ni ọ́ ní ọ̀nà mìíràn. Mo mọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní Juu ń sọ, àwọn tí kì í sì í ṣe Juu; tí ó jẹ́ pé ilé ìpàdé Satani ni wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ipọnju, ati aini rẹ (ṣugbọn ọlọ́rọ̀ ni ọ) emi si mọ̀ ọ̀rọ-òdi si Ọlọrun ti awọn ti nwipe Ju li awọn tikarawọn, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃, ṣugbọn ti nwọn jẹ́ sinagogu ti Satani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́ èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé Júù ni àwọn tìkárawọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ sínágọ́gù ti Sátánì.