Revelation 20:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí wọ́n kú sinu òkun tún jáde sókè. Gbogbo òkú tí ó wà níkàáwọ́ ikú ati àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú ni wọ́n tún jáde. A wá ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Okun si jọ awọn okú ti mbẹ ninu rẹ̀ lọwọ; ati ikú ati ipo-okú si jọ okú ti o wà ninu wọn lọwọ: a si ṣe idajọ wọn olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́; àti òkú àti ipò-òkú sì jọ̀wọ́ òkú tí ó wà nínú wọn pẹ̀lú: a sì ṣe ìdájọ́ wọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.