Revelation 20:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ri awọn ìtẹ́, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ri ọkàn awọn ti a ti bẹ́ lori nitori ẹrí Jesu, ati nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ̀, tabi ti kò si gbà àmi rẹ̀ ni iwaju wọn ati li ọwọ́ wọn; nwọn si wà lãye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọn: mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jésù, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà àmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹ̀lú Kírísítì ní ẹgbẹ̀rún ọdún.