Revelation 20:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan Ọlọrun tí ó bá ní ìpín ninu ajinde kinni ṣe oríire. Ikú keji kò ní ní àṣẹ lórí wọn. Wọn óo jẹ́ alufaa Ọlọrun ati ti Kristi, wọn óo sì jọba pẹlu rẹ̀ fún ẹgbẹrun ọdún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olubukun ati mimọ́ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mã jọba pẹlu rẹ̀ li ẹgbẹ̀run ọdún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olúkúlùkù àti mímọ́ ni ẹni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní náà: lórí àwọn wọ̀nyí ikú eekejì kò ní agbára, ṣùgbọ́n wọn ó jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kírísítì, wọn ó sì máa jọba pẹ̀lú rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún.