Revelation 20:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo wá tún jáde lọ láti máa tan àwọn eniyan jẹ ní igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé. Yóo kó gbogbo eniyan Gogu ati Magogu jọ láti jagun, wọn óo pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si jade lọ lati mã tàn awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni igun mẹrẹrin aiye jẹ, Gogu ati Magogu, lati gbá wọn jọ si ogun: awọn ti iye wọn dabi iyanrìn okun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gógù àti Mágógú, láti gbá wọn jọ sí ogun: àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn òkun.