Revelation 21:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Odi ìlú náà nípọn, ó sì ga. Ó ní ìlẹ̀kùn mejila, àwọn angẹli mejila wà níbi àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. A kọ àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli mejila sí ara àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ni odi nla ati giga, o si ni ẹnubode mejila, ati ni awọn ẹnubode na angẹli mejila ati orukọ ti a kọ sara wọn ti iṣe orukọ awọn ẹ̀ya mejila ti awọn ọmọ Israeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu-bodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu-bodè náà áńgẹ́lì méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;