Revelation 21:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si gbọ́ ohùn nla kan lati ori itẹ́ nì wá, nwipe, Kiyesi i, agọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mã ba wọn gbé, nwọn o si mã jẹ enia rẹ̀, ati Ọlọrun tikararẹ̀ yio wà pẹlu wọn, yio si mã jẹ Ọlọrun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkararẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn.