Revelation 21:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn ojo, àwọn alaigbagbọ, àwọn ẹlẹ́gbin, àwọn apànìyàn, àwọn àgbèrè, àwọn oṣó, àwọn abọ̀rìṣà, ati gbogbo àwọn èké ni yóo ní ìpín wọn ninu adágún iná tí ń jó, tí a fi imí-ọjọ́ dá. Èyí ni ikú keji.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè, ati oṣó, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ní ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fí iná àti súfúrù jó: èyí tí i ṣe ikú kéjì.”