Revelation 21:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí ó mú àwo meje lọ́wọ́, tí ìparun ìkẹyìn meje wà ninu wọn, ó wá bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní “Wá, n óo fi iyawo Ọ̀dọ́ Aguntan hàn ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkan ninu awọn angẹli meje nì, ti nwọn ni ìgo meje nì, ti o kún fun iyọnu meje ikẹhin si wá, o si ba mi sọ̀rọ wipe, Wá nihin, emi o fi iyawo, aya Ọdọ-Agutan, hàn ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì méje, tí wọ́n ni ìgò méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìnín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-Àgùntàn hàn ọ́.”