Revelation 22:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Èmi Jesu ni mo rán angẹli mi láti jíṣẹ́ gbogbo nǹkan wọnyi fún ẹ̀yin ìjọ. Èmi gan-an ni gbòǹgbò ati ọmọ Dafidi. Èmi ni ìràwọ̀ òwúrọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi Jesu li o rán angẹli mi lati jẹri nkan wọnyi fun nyin niti awọn ijọ. Emi ni gbòngbo ati iru-ọmọ Dafidi, ati irawọ owurọ̀ ti ntàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi, Jésù, ni ó rán ańgẹ́lì mi láti jẹ̀rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòngbò àti irú-ọmọ Dáfídì, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”