Revelation 22:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó gba ààrin títì ìlú náà. Igi ìyè kan wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ òsì odò náà. Igi ìyè yìí ń so èso mejila, ọ̀kan ní oṣooṣù. Ewé igi náà wà fún ìwòsàn àwọn orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ãrin igboro rẹ̀, ati niha ikini keji odò na, ni igi iye gbé wà, ti ima so onirũru eso mejila, a si mã so eso rẹ̀ li oṣõṣù: ewé igi na si ni fún mimú awọn orilẹ-ède larada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àárin ìgboro rẹ̀, àti níhà ìkínní kéjì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so oníruurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà.