Revelation 3:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti iwọ ti pa ọ̀rọ sũru mi mọ́, emi pẹlu yio pa ọ mọ́ kuro ninu wakati idanwo ti mbọ̀wa de ba gbogbo aiye, lati dán awọn ti ngbe ori ilẹ aiye wo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.