Revelation 3:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni a óo wọ̀ ní aṣọ funfun bẹ́ẹ̀. N kò ní pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò ninu ìwé ìyè. N óo jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi ati níwájú àwọn angẹli rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o ba ṣẹgun, on na li a o fi aṣọ funfun wọ̀; emi kì yio pa orukọ rẹ̀ rẹ́ kuro ninu iwe ìye, ṣugbọn emi o jẹwọ orukọ rẹ̀ niwaju Baba mi, ati niwaju awọn angẹli rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.