Revelation 3:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo fi àwọn kan láti inú ilé ìpàdé Satani lé ọ lọ́wọ́, àwọn òpùrọ́ tí wọn ń pe ara wọn ní Juu, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í ṣe Juu. N óo ṣe é tí wọn yóo fi wá sọ́dọ̀ rẹ, wọn yóo foríbalẹ̀ fún ọ, wọn yóo sì mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, emi o mú awọn ti sinagogu Satani, awọn ti nwọn nwipe Ju li awọn, ti nwọn kì si iṣe bẹ̃, ṣugbọn ti nwọn nṣeke; kiyesi i, emi o mu ki nwọn wá wolẹ niwaju ẹsẹ rẹ, ki nwọn si mọ pe emi ti fẹ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíyèsí i, èmi ó mú àwọn ti sínágógù Sàtánì, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké; kíyèsí i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹṣẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ.