Revelation 4:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Oluwa Ọlọrun wa, ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ògo, ati ọlá ati agbára. Nítorí ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, ati pé nípa ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, nípa rẹ ni a sì ṣe dá wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa, iwọ li o yẹ lati gbà ogo ati ọlá ati agbara: nitoripe iwọ li o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ inu rẹ ni nwọn fi wà ti a si dá wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Olúwa, ìwọ ni o yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára: nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni wọn fi wà tí a sì dá wọn.”