Revelation 4:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà ní apá mẹfa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọpọlọpọ ojú. Wọn kì í sinmi tọ̀sán-tòru, wọ́n ń wí pé, “Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́! Oluwa Ọlọrun Olodumare. Ẹni tí ó ti wà, tí ó wà nisinsinyii, tí ó sì ń bọ̀ wá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹda alaye mẹrin na, ti olukuluku wọn ni iyẹ́ mẹfa, kun fun oju yika ati ninu: nwọn kò si simi li ọsán ati li oru, wipe, Mimọ́, mimọ́, mimọ́, Oluwa Ọlọrun Olodumare, ti o ti wà, ti o si mbẹ, ti o si mbọ̀wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn-ań àti lóru, láti wí pé: “Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́, Olúwa Ọlọ́run Olódùmare, tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!”