Revelation 5:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bá tún gbọ́ tí gbogbo ẹ̀dá tí ó wà lọ́run ati ní orílẹ̀ ayé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀, ati lórí òkun, ati ohun gbogbo tí ń bẹ ninu òkun, ń wí pé, “Ìyìn, ọlá, ògo, ati agbára ni ti ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ati Ọ̀dọ́ Aguntan lae ati laelae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ẹda ti o si mbẹ li ọrun, ati lori ilẹ aiye, ati nisalẹ ilẹ, ati irú awọn ti mbẹ ninu okun, ati gbogbo awọn ti mbẹ ninu wọn, ni mo gbọ́ ti nwipe, Ki a fi ibukún ati ọlá, ati ogo, ati agbara, fun ẹniti o joko lori itẹ́ ati fun Ọdọ-Agutan na lai ati lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ẹ̀dá tí o sì ń bẹ ni ọ̀run, àti lórí ilẹ̀ ayé, àti nísàlẹ̀ ilẹ̀ àti irú àwọn tí ń bẹ nínú òkun, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú wọn, ni mo gbọ́ tí ń wí pé, “Kí a fi ìbùkún àti ọlá, àti ògo, àti agbára, fún Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà láé àti láéláé.”