Revelation 5:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si gbà iwe na, awọn ẹda alãye mẹrin na, ati awọn àgba mẹrinlelogun na wolẹ niwaju Ọdọ-Agutan na, olukuluku nwọn ní dùru ati ago wura ti o kún fun turari ti iṣe adura awọn enia mimọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú háàpù kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́.