Revelation 5:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n wá ń kọ orin titun kan, pé, “Ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ìwé náà, ati láti tú èdìdì ara rẹ̀. Nítorí wọ́n pa ọ́, o sì ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ bá Ọlọrun ṣe ìràpadà eniyan, láti inú gbogbo ẹ̀yà, ati gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si nkọ orin titun kan, wipe, Iwọ li o yẹ lati gbà iwe na, ati lati ṣí èdidi rẹ̀: nitoriti a ti pa ọ, iwọ si ti fi ẹ̀jẹ rẹ ṣe ìrapada enia si Ọlọrun lati inu ẹyà gbogbo, ati ède gbogbo, ati inu enia gbogbo, ati orilẹ-ède gbogbo wá;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé: “Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà, àti láti ṣí èdìdì rẹ̀: nítorí tí a tí pa ọ, ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo, àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá: