Revelation 6:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo rí Ọ̀dọ́ Aguntan náà nígbà tí ó ń tú ọ̀kan ninu àwọn èdìdì meje náà. Mo gbọ́ tí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin wí pẹlu ohùn tí ó dàbí ààrá, pé, “Wá!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
EMI si ri nigbati Ọdọ-Agutan na ṣí ọ̀kan ninu èdidi wọnni, mo si gbọ́ ọ̀kan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì nwi bi ẹnipe sisan ãrá pe, Wá, wò o.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà sí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, “Wá, wò ó!”