Revelation 6:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A wá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ funfun. A sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi díẹ̀ sí i títí iye àwọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ wọn ati àwọn arakunrin wọn yóo fi pé, àwọn tí wọn yóo pa láìpẹ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pa àwọn ti iṣaaju.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si fi aṣọ funfun fun gbogbo wọn; a si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o simi di ìgba diẹ na, titi iye awọn iranṣẹ ẹlẹgbẹ ati arakunrin wọn ti a o pa bi wọn, yio fi pé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí ó ti pa bí wọn, yóò fi dé.