Revelation 6:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọba ayé, àwọn ọlọ́lá, àwọn ọ̀gágun, àwọn olówó, àwọn alágbára, ati gbogbo eniyan: ẹrú ati òmìnira, gbogbo wọn lọ sápamọ́ sinu ihò òkúta ati abẹ́ àpáta lára àwọn òkè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọba aiye ati awọn ọlọlá ati awọn olori ogun, ati awọn ọlọrọ̀ ati awọn alagbara, ati olukuluku ẹrú, ati olukuluku omnira, si fi ara wọn pamọ́ ninu ihò-ilẹ, ati ninu àpata ori òke:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olókúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè;